Description
Nípa Òǹkọ̀wé
A bí Ọ̀gbẹ́ni Adùnadé Àmọ̀ó ní ìlú Ìwó. Ó lọ sí ilé ìwé alákoobẹ̀rẹ̀ ní ilé ìwé D.C. School Arárọ̀mí ní ìlú Ìwó kí o tó gba ilé ìwé oníwèé mẹ́wàá àwọn àgùdà lọ ní ìlú Òṣogbo, èyíun ní St. Charles Grammar School. Kò pẹ́ púpọ̀ tí o fí kúrò lọ sí ilé ìwé oníwèé mẹ́wàá mìíràn ní ìlú Ìwó èyíun ní Ìwó Grammar School. Lẹ́hìn tí ó parí ìwé mẹ́wàá ni ó gba ilé ìwé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ ní Ilé-Ifẹ̀ (University of Ife – tí ó di Obafemi Awolowo University) báyìí. Ibẹ̀ ní ó sì tí gba oyè Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ nínú Ìtàn. Ó tún kọ́ ẹkọ́ nínú èdè Yorùbá bákan náà. Ó tún lọ sí ilé ẹkọ́ ètò ìṣàkóso ní ìlú Òyìnbó níbi tí ó tí gba ìwé ẹ̀rí nínú ètò Ìṣàkóso. Lẹ́hìn tí ó ṣe èyí tán ní ó tún padà sí ilé ìwé Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ní Ilé-Ifẹ̀ tí ó tún ti gba oyè ẹ̀ẹ̀kejì nínú ètò Ìṣàkóso.
Ọ̀gbẹ́ni Adùn Àmọ̀ó ní ìyàwó, Ọlọ́run sì fi àwọn ọmọ rere taá lọ́rẹ.







Reviews
There are no reviews yet.