Description
Ọmọ méjì wọ́kú l’ẹ́ẹ̀kan náà fún Ààrẹ-Àgò. Ó ní kí wọ́n lọ wádìí eku ẹdá tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà. Ìyáálé fi ọ̀ràn bọ ìyàwó rẹ̀ lọ́rùn. Lójijì ni ọmọ kẹta fò sánlẹ̀ tó tún kú. Ààrẹ-Àgò bínú, ó pìtú tíí pa l’ójú ogun. Òkú sùn! Ọ̀ràn dé! Ẹjọ́ dé wájú Baṣọ̀run Ògúnmọ́lá, ìdájọ́ ńlá ṣẹlẹ̀!
Taa ló dá ẹ̀mí ọmọ mẹ́ta l’ẹ́gbodò? Kí ló fà á tí Ààrẹ-Àgò fi di Aríkúyẹrí? Ìdáhùn wà nínú ìtàn olóyin mọmọ yìí.
A ti fi àkọtọ́ èdè Yorùbá òde-òní gbé Ààrẹ-Àgò Aríkúyẹrí lárugẹ fún àkàgbádùn àwọn ọmọ ilé-ìwé àti àwọn olùfẹ́ èdè Yorùbá.







Reviews
There are no reviews yet.