Description
Ilé-iṣé atẹwétà Francis Heritage Publishers fẹ́ láti rí i pé àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ aláàkọ́bẹ̀rẹ̀ ní ìmọ̀ nípa òwe Yorùbá nípa kíkà, kí kọ àti lílò òwe lọnà tí ó rọrùn, tó sì wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Kúríkúlọ́mù fún kíkọ èdè Yorùbá tí Àjọ Nigerian Educational Research and Development Council (NERDC) fi lélẹ̀. Ìdì níyì tí a fi gbé àwọn ìwé Òwe Ilé Baba Wa jáde fún àǹfààní àwọn ọmọ wa.
Òwe kan sọ pé: “Ọ̀rịṣà tí a ń sin tí a ń lé ọmọdé sẹ́yìn, ọ̀rịṣà náà kò ní pé parun”. A fẹ́ kì àwọn ọmọdé lè pa òwe ké-kèké tó bá gbón àti ìrí rí wọn mu. Bí àwọn àgbà bá ń pa òwe nínú ìpàdé wọn tàbí láàárín ẹni kan sí èkèjì, ọmọdé tó bá ń gbọ́ òwe a ó lè ní òye ohun tí wọ́n ń sọ ní tọ rí pé òwe kì í ṣe a jẹ̀jì sí òun paápáà.
Ìwé Òwe Ilé Baba Wa láti Alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kejì títì dé Alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kẹfà ni a tẹ̀ jáde fún ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ aláàkọ́bẹ̀rẹ̀.









Reviews
There are no reviews yet.