Description
Iwẻ yií je àkójopò ese Ifá ti a mú láti inú àwon Ojú Odù (Olojà) Mérèerindinlógún. A mú ese Ifá méjo-méjo láti inů Odù kookan bèrè láti inú Eji Ogbè títi tí ó fi kan Ofün (Oràngún) Méji. lyàtò ti ở wà nínú iwé yii àti àwon iwé Ifá ati ewi àdáyébá miiràn ni pé a se àlàyé ese Ifå kòòkan tiń bẹ ninú iwé yii léseese. A se èyí nitori pé ati şe àkiyèsi wi pé àwon ese Ifá wonyí kii yé àwon akékoo àti olùkó náà dáadáa nigbà tí won bá ń kà won. Edè àtayé báyé ni èdè Orúnmilà. Nitorí náa kò ya ‘ni lénu wipé èdè lIfá ki í tètè yé ogbèri. ldi niyí ti a fi se àlàyé sókisókí lóri esę koökan. Fún eni ti ó bá ni òye ti ó si ní ife si ese Ifä, a lérò pé àlàyé wònyi ó jèe ilànà pàtäki nigbà ti ó bań ka iwé yii finífini. Ni ibère iwé yii, a se àlàyé nipa ohun ti Ifa je gége bi orisà àti ewi àdáyébá Yorùbá. A lérò wi pé àlàyé yii náà ó ran àwỌn ònkàwé wa lówó láti mo ipò ti Ifá kó ninú ogbộn, imò àti iríri omo Yorùbá.
Reviews
There are no reviews yet.